Oriki Ṣango🤴🏿❤️🔥🪓 Ṣango oluaṢo, akata yeriyeri Oloju orogbo Eleeke obi Olukoso, eegun ti n yona lenu OoṢa ti nba ologbo leru Ṣango a benu jijadu eku Eni foju di ó Ṣango alaṢo Osun, Onile olá Oninalenu AṢode bi ologbo Ṣangiri lagiri Olagiri kaka figba edun bó Bi won ti n pariwo re nile Bee ni won n pariwo re logun Ṣango onã ya si meji ókó onikêlê Pa wõn pó, o fi sokõn Okunrin ogun Okunrin kenke niwaju onibátá Ojo peborá le guréguré Ati lojo, ati lérun Ko séni ti olukoso o le pa A lomó olomõ molé bi a nlowu irin Oju Ṣu, oju o Ṣu Ko séni ti olukoso o lê pá A gbomi mú bi alapá Dákun Ṣango má pá mi Máá si pá eniyan si mi lorun Bá mi Ṣegún otá Bá mi womo Máá jé kí ndarãn omodé Máá jé kí ndarãn agbalagba Máá jé n lúfín ijóbá Máá jé n rín-irín A rín fésé kó Máá jé n fénú mi kó Ṣango olukoso a pá ní má yoda Kabiyesi o Ókó mí Ábitámará bi ahêrê Atô bá jáyê ooooo Obá koso Ma fi oṢe re nã emí ati awõn ebí mi Olukoso atôbájayê, Ṣo mi nínú won
Oriki Ṣango🤴🏿❤️🔥🪓
Ṣango oluaṢo, akata yeriyeri
Oloju orogbo
Eleeke obi
Olukoso, eegun ti n yona lenu
OoṢa ti nba ologbo leru
Ṣango a benu jijadu eku
Eni foju di ó
Ṣango alaṢo Osun, Onile olá
Oninalenu
AṢode bi ologbo
Ṣangiri lagiri
Olagiri kaka figba edun bó
Bi won ti n pariwo re nile
Bee ni won n pariwo re logun
Ṣango onã ya si meji ókó onikêlê
Pa wõn pó, o fi sokõn
Okunrin ogun
Okunrin kenke niwaju onibátá
Ojo peborá le guréguré
Ati lojo, ati lérun
Ko séni ti olukoso o le pa
A lomó olomõ molé bi a nlowu irin
Oju Ṣu, oju o Ṣu
Ko séni ti olukoso o lê pá
A gbomi mú bi alapá
Dákun Ṣango má pá mi
Máá si pá eniyan si mi lorun
Bá mi Ṣegún otá
Bá mi womo
Máá jé kí ndarãn omodé
Máá jé kí ndarãn agbalagba
Máá jé n lúfín ijóbá
Máá jé n rín-irín
A rín fésé kó
Máá jé n fénú mi kó
Ṣango olukoso a pá ní má yoda
Kabiyesi o
Ókó mí
Ábitámará bi ahêrê
Atô bá jáyê ooooo
Obá koso
Ma fi oṢe re nã emí ati awõn ebí mi
Olukoso atôbájayê, Ṣo mi nínú won