Oríkì Ìlú Ìjẹ̀bú|The Eulogy of Ijebu Town|AbalayeTV
Вставка
- Опубліковано 22 гру 2024
- Ìjẹ̀bú ọmọ Alárẹ̀,
Ọmọ Bíbíire è é è jú fowórà,
Ọmọ Aṣàlèjẹ̀jẹ̀ bọ́ọni nòóbìnrin,
Ẹ̀yin ọmọLúwàbí,
Ọmọ Olú-ìwà,
Ọmọ Ọbańta,
Ọmọ Alárẹ̀.
Ọmọ Alágẹmọ-ò-tú-yọ̀wọ̀yọ̀wọ̀.
Ọmọ b'épè ò jà mọ́,
Má yáa wóhun mín ìn tún ṣe.
Ìjẹ̀bú ọmọ Arójòjoyè.
Ọmọ Awúre fàṣẹ banu.
Ọmọ olówó joyè méjì pọ̀.
Olówó ṣílè ṣá lẹ̀yin,
Kékeré Ìjẹ̀bú, owó ni.
Àgbà Ìjẹ̀bú, owó ni.
Ọmọ Àrígbá-ńlá-buwó,
Ọmọ A fọ́nwó bí ẹ ń fọ́n yangan.
Ìjẹ̀bú ọmọ A-fìdí-pọ̀tẹ̀ mọlẹ̀.
Iṣu mẹ́fà nisu Ìjẹ̀bú,
Wọ́n ta méjì,
Wọ́n jẹ méjì síkùn ara wọn,
Ó l'órìṣà tí wọ́n fi méjì yókù bọ.
Ọmọ ẹlẹ́dìẹ òkòkòmàgà,
Èyí tí ń mingbó kìjikìji.
Ọmọ ohun ń ṣe ni ọ̀yọ̀yọ̀ ń yọ̀,
Ọ̀yọ̀yọ̀ má yọ̀ má yọ̀ mọ́,
Ohun tó ń ṣeni ò ní lè pani.
Ọmọ Ọlọ́pẹ kan ọ̀jẹ́gẹ́tirígẹ́,
Ọmọ Ọlọ́pẹ kan ọ̀jẹ̀gẹ̀tirígẹ̀,
Kò ga jù, bẹ́ẹ̀ ni kò kúrú,
Ó ń fọwọ́ imọ̀ gbálẹ̀ gẹẹrẹgẹ.
Afínjú Ìjẹ̀bú tí í fọkọ ẹ̀ j'Apènà.
Ààyè gbà'Jẹ̀bú,
Ó wẹní rẹ wínníwínní,
Ààyè gbà' Jẹ̀bú,
Ó wẹní rẹ ní wìnnìwìnnì,
Ààyè gbọmọ Ògbòrògànlúdà,
Ó bẹ́mọ lórí rẹ̀gí rẹ̀gí.
A-bọ́lọ́mọ-jà-bí-ò-pọnmọ-re,
Ẹ̀rù jẹ̀jẹ̀ ọmọ Ò-gboko-gbààlà.
Lyrics by: Lawanson, O. (2010). Àwọn Oríkì Mẹ́ta Ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ; Lagos : Afbax Communications.
Video by: Abalaye Naijiria
Music by: Ebenezer Obey